Igboran San
mar100.PNG

          Ni akoko kan n’ilu Oloke-meje, Eni-ibukun, alufa orisa Atinuke ranse ikilo si afin oba pe, fun ojo meje, enikan ko gbodo rinde ale, ope ju ago meje, kolu kuluku ti wa n’ile re. kabiyesi ti kin fi ikilo Atinuke sere ripe ise nan jade ni kia kia fun awon eniyan ilu. ‘ Fun ojo meje bere lati ola, ko seni to gbudo rin ni ale. Lati aago meje soke, ko luku luku ti wani ile re.’ Kabiesi ro won osi be awon to mon pe kan jo, kan gboran. Sugbon emo wipe, ka f’inan wasun, omo orun apadi yoo lo. Awon ti yo gbo ran joko sile, won o je ki ago meje lu ba won nita. Won a soro, sere, to basi ya, won alo sun. Fun ojo meje pere, mi oro pe opo ju.
          Awon kan na si wa tan gbon ju ogbon lo. Lara won ni Adeniyi, omo Adekola. Oni ti Atinuke lon so yen, oni lati ojo alaye ti daye ni eniyan ti rin lale. Ohun o ran omo eni kan nise, ohun yoo se to hun n’ile yi. Koburu! Ohun se tie. Lale ojo kefa botin rin irin aigbonran e lo, lode orita  meta kan bi ese ogun sile re, ori eda kan nibe, ko se eniyan, ko seran ko. Oni ori eniyan, oni ara bi ti ejo, oni iye bi tasa, oni ese bi ti kininu. Lookan, oda bi pe kosi ohun kan nibe, nisisun mon, imole re fe le fo loju. Nigba ti Adeniyi sunmo, eru ba, se lo da bi kowo ile, ohun ikeyin to fojuri  niyen. Be nan ni enu re yadi.
          Ibi to joko si ni awon eniyan re ti wa gbe laro ojo keji. Ah! Adeniyi, oju re kan ran saa ni, ko le rin nkan kan. Bo batun ni kohun soro, afefe lon jade. Awon ebire bere  sini sare ka. Won fe gba sile, wo sare ka kiri sugbon won o ri ohun ri se si. Won wa ba Eni-ibunkun ko jo ko ba won be iya Atinuke ko saanu Adeniyi, ohun ebo ti iya ba bere won se tan lati mu wa. Eni-ibukun so fun won pe, igbora san ju ebo riru, ohun kori nkan se si. Bi ohun ba lo ba iya Atinuke lori oro naa, beni pe ohun danwo ni. Ibinu iya osi da. Kosi sise, eba ti san ki Adeniyi ti gboran, nigba to siti ko, o ti ri ohun ti ko ye. Be ni yo wa titi ti yo fi ku.
 

244 views
0 comments
one year ago
No Episodes in this story
No comment on this Story
You have to be Logged in to add a comment